Isaiah 58:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ, ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde. Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó, alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn tirẹ yio mọ ibi ahoro atijọ wọnni: iwọ o gbé ipilẹ iran ọ̀pọlọpọ ró, a o si ma pe ọ ni, Alatunṣe ẹyà nì, Olumupada ọ̀na wọnni lati gbe inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú un rẹ̀.