Isaiah 58:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA, n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gùn ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ níni Jakobu baba rẹ bọ́ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú OLÚWA rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jákọ́bù baba rẹ.” Ẹnu OLÚWA ni ó ti sọ̀rọ̀.