Isaiah 58:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ, wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi, wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo, tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀. Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi, wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nwọn nwá mi lojojumọ, nwọn si ni inu didun lati mọ̀ ọ̀na mi, bi orilẹ-ède ti nṣe ododo, ti kò si fi ilàna Ọlọrun wọn silẹ: nwọn mbere ilàna ododo wọnnì lọwọ mi; nwọn a ma ṣe inu didun ati sunmọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri; wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi, àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀. Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.