Isaiah 58:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa? Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?” OLUWA wí pé, “Ìdí rẹ̀ ni pé, nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín. Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kini awa ṣe ngbãwẹ̀, ti iwọ kò si ri i? nitori kini awa jẹ ọkàn wa ni ìya, ti iwọ kò si mọ̀? Kiyesi i, li ọjọ ãwẹ̀ nyin ẹnyin nṣe afẹ́, ẹ si nfi agbara mu ni ṣe gbogbo iṣẹ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí, ‘tí ìwọ kò sì tí ì rí? Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ní ọjọ́ ààwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.