Isaiah 58:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín, ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà. Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ẹnyin ngbãwẹ̀ fun ìja ati ãwọ̀, ati lilù, nipa ikũku ìwa-buburu: ẹ máṣe gbãwẹ bi ti ọjọ yi, ki a le gbọ́ ohùn nyin li oke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ààwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pẹ̀lú ẹṣẹ́ ìkà. Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.