Isaiah 58:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé: kí á tú ìdè ìwà burúkú, kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà; kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, kí á já gbogbo àjàgà?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ irú ààwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìsòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?