Isaiah 58:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín, bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó, kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòsì tí ń rìn káàkiri nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran yín sẹ́yìn?