Isaiah 58:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, n óo sì da yín lóhùn. Ẹ óo kígbe pè mí, n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ “Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín, tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́, tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí OLÚWA yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí. “Bí ẹ̀yin bá mú àjàgà aninilára kúrò, pẹ̀lú ìka àléébù nínà àti ọ̀rọ̀ ìṣáátá,