Isaiah 59:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo bẹ̀rù orúkọ OLUWA láti ìwọ̀ oòrùn, wọn óo bẹ̀rù ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn; nítorí yóo wá bí ìkún omi, tí ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń taari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si bẹ̀ru orukọ Oluwa lati ìwọ-õrùn wá, ati ogo rẹ̀ lati ilà-õrun wá. Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ OLÚWA, àti láti ìlà oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀. Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi èyí tí èémí OLÚWA ń tì lọ.