Isaiah 59:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niti emi, eyi ni majẹmu mi pẹlu wọn, ni Oluwa wi; Ẹmi mi ti o wà lara rẹ̀, ati ọ̀rọ mi ti mo fi si ẹnu rẹ, kì yio kuro li ẹnu rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ ọmọ rẹ, ni Oluwa wi, lati isisiyi lọ ati lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni OLÚWA wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni OLÚWA wí.