Isaiah 59:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre, kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo. Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé. Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín, iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ẹni tí ó bèèrè fún ìdájọ́ òdodo; kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n gbọ́kànlé àwíjàre aṣán àti ọ̀rọ̀ irọ́; wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà