Isaiah 59:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan bá dáhùn pé, “Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa, tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà. Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú, ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bolẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori na ni idajọ jìna si wa, bẹ̃ni ododo kì yio le wa bá, awa duro dè imọlẹ, ṣugbọn kiyesi i, okunkun, a duro de imọlẹ, ṣugbọn a nrin ninu okunkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa, àti tí òdodo kò fi tẹ̀wá lọ́wọ́. A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ jẹ́ òkùnkùn; fún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.