Isaiah 6:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?” Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni emi wipe, Oluwa, yio ti pẹ to? O si dahùn pe, Titi awọn ilu-nla yio fi di ahoro, li aisi olugbe, ati awọn ile li aisi enia, ati ilẹ yio di ahoro patapata.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó OLÚWA?” Òun sì dáhùn pé: “Títí tí gbogbo ìlú ńlá yóò fi dahoro láìsí olùgbé nínú un rẹ̀ mọ́, títí tí gbogbo ilé yóò fi di ìkọ̀sílẹ̀ tí gbogbo ilé yóò sì di àlàpà àti ahoro,