Isaiah 6:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo wipe, Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jẹ́ ẹni alaimọ́ etè, mo si wà lãrin awọn enia alaimọ́ etè, nitoriti oju mi ti ri Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ègbé ni fún mi!” Ni mo ké, “Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrin àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun jùlọ.