Isaiah 60:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ, àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ; nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́. Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ìkannu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣãnu fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn àjèjì yóò tún ògiriì rẹ mọ àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́, ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.