Isaiah 60:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá, wọn óo tẹríba fún ọ; gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ, yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ; wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA, Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọkunrin awọn aninilara rẹ pẹlu yio wá ni itẹriba sọdọ rẹ; gbogbo awọn ti o ti ngàn ọ, nwọn o tẹ̀ ara wọn ba silẹ li atẹlẹsẹ rẹ; nwọn o si pe ọ ni Ilu Oluwa, Sioni ti Ẹni-Mimọ́ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò wá foríbalẹ̀ fún ọ; gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ wọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú OLÚWA, Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.