Isaiah 60:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè, o óo mu wàrà àwọn ọba. O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ, ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o mu wàra awọn Keferi, iwọ o si mu ọmu awọn ọba; iwọ o si mọ̀ pe, emi Oluwa ni Olugbala rẹ, ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara Jakobu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdè a ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi OLÚWA, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì.