Isaiah 60:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo, àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae. Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, kí á baà lè yìn mí lógo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn enia rẹ, gbogbo wọn o jẹ olododo: nwọn o jogun ilẹ na titi lailai, ẹka gbigbin mi, iṣẹ ọwọ́ mi, ki a ba le yìn mi logo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé. Àwọn ni èhù tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọlá ńlá mi hàn.