Isaiah 60:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbé ojú sókè kí o wò yíká, gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè, a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká rẹ: Gbogbo wọn gbárajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn, àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrìn rẹ ni a gbé ní apá.