Isaiah 60:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí o bá rí wọn, inú rẹ yóo dùn, ara rẹ óo yá gágá. Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀, nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fó yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá.