Isaiah 60:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká, àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa. Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá, wọn óo mú wúrà ati turari wá; wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀pọlọpọ rakunmi yio bò ọ mọlẹ, awọn ọmọ rakunmi Midiani on Ẹfa; gbogbo wọn o wá lati Ṣeba: nwọn o mu wura ati turari wá; nwọn o fi iyìn Oluwa hàn sode.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀wọ́ ràkunmí yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ràkunmí Mídíánì àti Ẹfà. Àti gbogbo wọn létí Ṣèbà yóò wá, wọn yóò mú Góòlù àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn OLÚWA.