Isaiah 60:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ẹran ọ̀sìn Kedari ni wọ́n óo kó wá fún ọ, wọn óo kó àgbò Nebaiotu wá ta ọ́ lọ́rẹ. Wọn óo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi, ilé mi lógo, ṣugbọn n óo tún ṣe é lógo sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o ṣà gbogbo ọwọ́-ẹran Kedari jọ sọdọ rẹ, awọn àgbo Nebaioti yio ṣe iranṣẹ fun ọ; nwọn o goke wá si pẹpẹ mi pẹlu itẹwọgba, emi o si ṣe ile ogo mi li ogo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo agbo ẹran Kédárì ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nébáíótì yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹ́ḿpìlì ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.