Isaiah 60:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí, ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwaju wọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè, wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn; nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ erekuṣu wọnni yio duro dè mi, ọkọ Tarṣiṣi wọnni li ekini, lati mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti ọ̀na jìjin wá, fadaka wọn, ati wura wọn pẹlu wọn, fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ, ati fun Ẹni-Mimọ́ Israeli, nitoriti on ti ṣe ọ logo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lótìítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn, pẹ̀lú fàdákà àti góòlùu wọn, fún ti ọlá OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.