Isaiah 61:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yio yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi agbáda wọ̀ mi, o ti fi aṣọ ododo bò mi, gẹgẹ bi ọkọ iyawó ti iṣe ara rẹ̀ lọṣọ́, ati bi iyawó ti ifi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọṣọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yọ̀ gidigidi nínú OLÚWA; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe oríi rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.