Isaiah 61:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde, tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori gẹgẹ bi ilẹ ti imu ẽhù rẹ̀ jade, ati bi ọgbà ti imu ohun ti a gbìn sinu rẹ̀ hù soke; bẹ̃ni Oluwa Jehofah yio mu ododo ati iyìn hù soke niwaju gbogbo orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú èhù jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè.