Isaiah 61:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónì láti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú, òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo, irúgbìn OLÚWA láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.