Isaiah 61:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín, àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alejò yio si duro, nwọn o si bọ́ ọwọ́ ẹran nyin, awọn ọmọ alejò yio si ṣe atulẹ nyin, ati olurẹ́ ọwọ́ àjara nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.