Isaiah 61:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA, àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn a o ma pè nyin ni Alufa Oluwa: nwọn o ma pè nyin ni Iranṣẹ Ọlọrun wa: ẹ o jẹ ọrọ̀ wọn Keferi, ati ninu ogo awọn li ẹ o mã ṣogo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó sì máa pè yín ní àlùfáà OLÚWA, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.