Isaiah 61:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́, mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́. Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn, n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi Oluwa fẹ idajọ, mo korira ijale ninu aiṣododo; emi o si fi iṣẹ wọn fun wọn ni otitọ, emi o si ba wọn da majẹmu aiyeraiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí Èmi, OLÚWA fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀ Ní òtítọ́ mi èmi yóò ṣẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúu wọn.