Isaiah 61:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè, a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan, gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn, yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o si mọ̀ iru wọn ninu awọn Keferi, ati iru-ọmọ wọn lãrin awọn enia, gbogbo ẹniti o ri wọn yio mọ̀ wọn, pé, iru-ọmọ ti Oluwa busi ni nwọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó mọ ìrandíran wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ìran wọn láàrin àwọn ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí OLÚWA ti bùkún.”