Isaiah 62:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá, ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan. Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà, kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀. Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kọja lọ, ẹ kọja li ẹnu bode; tun ọ̀na awọn enia ṣe; kọ bèbe, kọ bèbe opopo; ṣà okuta wọnni kuro, gbe ọpagun ró fun awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà! Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn. Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó! Ẹ sa òkúta kúrò Ẹ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè