Isaiah 62:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́, “Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́, a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.” Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ, ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfísíbà, àti ilẹ̀ rẹ ní Béúlà; nítorí OLÚWA yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.