Isaiah 62:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ. Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti igbé wundia ni iyawo, bẹ̃ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio gbe ọ ni iyawo: ati bi ọkọ iyawo ti iyọ̀ si iyawo, bẹ̃ni Ọlọrun rẹ yio yọ̀ si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lóríì rẹ.