Isaiah 62:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra, ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́, pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ, ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́; àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ, tí o ṣe wahala lé lórí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ti fi apá ọtun rẹ̀, ati apá agbara rẹ̀ bura, Lõtọ emi kì yio fi ọkà rẹ ṣe onjẹ fun awọn ọta rẹ mọ, bẹ̃ni awọn ọmọ ajeji kì yio mu ọti-waini rẹ, eyi ti iwọ ti ṣíṣẹ fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ti búra pẹ̀lú ọ̀tún rẹ̀ àti nípa agbára apá rẹ: “Èmi kì yóò jẹ́ kí hóró rẹ di oúnjẹ fún ọ̀tá rẹ bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnì tuntun rẹ mọ́ èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;