Isaiah 62:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́, wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA; àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀, ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ti o ṣà a jọ yio jẹ ẹ, nwọn o si yìn Oluwa; ati awọn ti nkó o jọ yio mu u, ninu ãfin mimọ́ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́ tí wọn ó sì yin OLÚWA, àti àwọn tí wọ́n bá kó gírépù jọ ni wọn ó mú un nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”