Isaiah 63:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí, tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira, tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀, tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.” “Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san, tí mo sì lágbára láti gbani là.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
TANI eleyi ti o ti Edomu wá, ti on ti aṣọ arẹpọ́n lati Bosra wá? eyi ti o li ogo ninu aṣọ rẹ̀, ti o nyan ninu titobi agbara rẹ̀? Emi ni ẹniti nsọ̀rọ li ododo, ti o ni ipá lati gbala.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta nì yìí tí ó ń bọ̀ láti Édómù, láti Bósírà, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí osùn ṣe àbàwọ́n fún Ta nì yìí, tí a wọ̀ ní aṣọ ẹ̀yẹ, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni bí, tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó nípa láti gbàlà.”