Isaiah 63:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́, ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀. Wọ́n bèèrè pé, ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà? Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀, tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni o ranti ọjọ atijọ, Mose, awọn enia rẹ̀, wipe, Nibo li ẹniti o mu wọn ti inu okun jade gbe wà, ti on ti olùṣọ agutan ọwọ́-ẹran rẹ̀? nibo li ẹniti o fi Ẹmi mimọ́ rẹ̀ sinu rẹ̀ gbe wà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mósè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn,