Isaiah 63:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ; tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ? Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ, nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, nitori kili o ṣe mu wa ṣina kuro li ọ̀na rẹ, ti o si sọ ọkàn wa di lile kuro ninu ẹ̀ru rẹ? Yipada nitori awọn iranṣẹ rẹ, awọn ẹya ilẹ ini rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èéṣe OLÚWA tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ? Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ẹ̀yà tíi ṣe ogún ìní rẹ.