Isaiah 63:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini, ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi. Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà, mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ: ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì; láti àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi. Mo tẹ̀wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.