Isaiah 63:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́, ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró; nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun, ibinu mi ni ó sì gbé mi ró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́. Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́; nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi àti ìrunú mi ni ó gbémiró.