Isaiah 63:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́, n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀; nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa, ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli, tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀, ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sọ nípa àánú OLÚWA ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún, gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLÚWA ti ṣe fún wa bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.