Isaiah 63:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni, angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là. Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada. Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu gbogbo ipọnju wọn, oju a pọn ọ, angeli iwaju rẹ̀ si gbà wọn: ninu ifẹ rẹ̀ ati suru rẹ̀ li o rà wọn pada; o si gbe wọn, o si rù wọn ni gbogbo ọjọ igbani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú un gbogbo ìpọ́njúu wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti ańgẹ́lì tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là. Nínú Ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà; ó gbé wọn ṣókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.