Isaiah 64:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù, tí ẹnikẹ́ni kò retí, o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí, o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ.