Isaiah 64:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.