Isaiah 64:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́, àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn, o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀, a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́. Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ayọ̀ ṣe ohun tótọ́, tí ó rántí ọ̀nà rẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn, inú bí ọ. Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?