Isaiah 64:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA má bínú pupọ jù, má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae. Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò, nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe bínú kọjá ààlà, Ìwọ OLÚWA: Má ṣe rántíi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.