Isaiah 65:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi, ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi. Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé, “Èmi nìyí, èmi nìyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A wá mi lọdọ awọn ti kò bere mi; a ri mi lọdọ awọn ti kò wá mi: mo wi fun orilẹ-ède ti a kò pe li orukọ mi pe, Wò mi, wò mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi; Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi. Sí àwọn orílẹ̀ èdè tí kò pe orúkọ mi, Ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’