Isaiah 65:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fi yín fún ogun pa, gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn; nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́, ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi; ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò yà ọ́ ṣọ́tọ̀ fún idà, àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa; nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn. Mo ṣọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tísílẹ̀ Ẹ̀yin ṣe búrurú ní ojú mi ẹ sì yan ohun tí ó bàmí lọ́kàn jẹ́.”