Isaiah 65:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn ebi yóo máa pa yín; àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini, ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀, ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí nìyìí: “Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun; ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin, àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu, ṣùgbọ́n òrùngbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin; àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀, ṣùgbọ́n a ó dójú ti ẹ̀yin.