Isaiah 65:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà, yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́, ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà, orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra. Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé, a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́; Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì farasin kúrò lójú mi.